Welcome to Lagos Multi-Door Courthouse

FAQ in Yoruba

Èèyàn lè wọlé tọ wọn wá,ẹnikẹ́ni t’ọ́rọ̀ bá kàn lè gbé ìgbésẹ̀ pípẹ̀tù -ṣááwọ̀, wọ́n lè yan èèyàn láti yanjú ááwọ̀ náà, nípa ètò gbígbé ẹjọ́ náà wá kíákíá tàbí ìgbésẹ̀ ìmíràn nípa kíkọ ìwé ránṣẹ́ s’ólùdarí Àjọ LMDC tàbí ṣíṣe àbẹ̀wò sáwọn ibùdó tí ó ńgbẹ́jọ́ tí wọ́n tọ́ka sí náà.

Adájọ́ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ẹjọ́ tí wọ́n gbé wá náà, tàbí lásìkò tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ náà lè sọ fún àwọn èèyàn tí wọ́n gbé ẹjọ́ náà wá pé, kí wọ́n gbẹ́jọ́ náà lọ tààràtà s’íbùdó tí ó ń mójútó irú àwọn ẹjọ́ bẹ́ẹ̀, Ìyẹn LMDC, ẹ̀wẹ́, Láwọn ibi t’ẹ́jọ́ náà tí jẹ́ èyí t’áwọn aráàlú nífẹ̀ẹ́ sí, tàbí èyí t’áwọn èèyàn tí wọ́n gbẹ́jọ́ náà wá fẹ́ kí wọ́n tètè ṣẹjọ́ náà, a óò b'áwọn tí wọ́n gbẹ́jọ́ náà wá sọ̀rọ̀ pé, a ó rán wọn lọ́wọ́ láti yanjú gbọ́n-mi-si-omi-ò-to tí ó ń ṣẹlẹ̀ láàrín wọn.

Láti p'ẹjọ́, ẹni tó fẹ́ fẹ́ pẹjọ́ ṣọwọ sí wọn, pe àkíyèsí ìwé ìpéjọ náà sí wọn, ìwé àdéhùn àwọn Olùpẹ̀jọ́ náà àtàwọn ìwé mìíràn tí yóò ṣ’àtìlẹyìn àwọn èyí tí wọ́n ti mú wá tẹ́lẹ̀ ṣọwọ́ sórí àdirẹ́sì ẹ̀rọ alátagbà wa, ìyẹn email.com tàbí kí wọ́n fúnrara wọn wá s’ọfíìsì wa tí ó wà nílùú Ìkẹjà fún àyẹ̀wò tó péye. Tí gbogbo ètò náà bá lọ déédéé, wọn yóò rọ àwọn èèyàn tí wọ́n gbẹ́jọ́ náà wá pé kí wọ́n san owó ráńpẹ́ àti ìgbésẹ̀ gbígba láti wá ẹni tí wọn yàn fún ìgbà díè tí yóò báwọn mójútó ẹjọ́ wọn nílé ẹjọ́ tí ó ń gbọ́ ẹjọ́ oríṣiríṣi .
BẸ́Ẹ̀NI OO! Látàrí àjàkálẹ̀ –ààrùn tí ó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2020, Àjọ LMDC bẹ̀rẹ̀ ètò yíyanjú ááwọ̀ lórí ẹ̀rọ alátagbà agbọ́rọ̀káyé tí yóò fààyè gba èèyàn kan, amòfin, ilé-iṣẹ́ láti gbẹ́jọ́ wá sílé-ẹjọ́ LMDC, níbikíbi tí wọ́n bá wà. Wọ́n lè fi fáìlì ìwé ìpẹ̀jọ́ ṣọwọ́ sórí ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé email (registry.lmdc@gmail.com ).

Ilé-ẹjọ́ tó ń tọ́ka sáwọn Ìlànà náà gbé ìgbésẹ̀ wíwọlé -tọ-wón-wá tí wọ́n yóò gbà kó nǹkan náà lórí ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé Ìlànà tí wọn yóò tẹ̀lé nìyí: http//forms.gle/LsuwPN1hYRbea9AW8.

Ètò ìpẹ̀tù -ṣááwọ̀ náà máa ń wáyé lórí ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé lójú-kojú tí a óò jọ máa sọ̀rọ̀ sí ara wa pẹ̀lú Ilé-Iṣẹ́ náà tún lè wáyé nípa lílo Email tabi WhatsApp fún àlàyé l’ẹ́kùnrẹ́rẹ́, ẹ lè bẹ ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé wa wò ìyẹn; www.lagosmultidoor.org.

Wọn yóò f’ìwé yí yanjú ááwọ̀ náà ráńṣẹ́ lórí ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé fáwọn èèyàn náà láti buwọ́lù. Bákan náà, níbi táwọn èèyàn náà kò sí lórílẹ̀-èdè yìí, àwọn èèyàn náà lè tọwọ́ bọ̀wé náà kí wọ́n tẹ ìwé tí wọ́n buwọ́lù náà ráńṣẹ́ sílé ẹjọ́ LMDC náà.
A).Owó ìṣàkóso: Wọn kìí gba irú owó báyìí padà nítorí pé, ó wà fún gbogbo ohun tí wọ́n fẹ́ mójútó nípa ọ̀rọ̀ ẹjọ́ náà.
B).Owó tí wọ́n yóò san nígbà tẹ́jọ́, náà bá ń lọ lọ́wọ́- lọ́wọ́, owó náà wà lórí bẹ́jọ́ náà bá ṣe níye lórí tó, bóyá wọ́n fẹ́ gba ẹni tí yóò pẹ̀tù -ṣááwọ̀ ní o, tàbí ẹni tí wọ́n yóò gbà fún ìgbà díẹ̀ tí yóò bá wọn yanjú ẹjọ́ náà tàbí ẹni tí yóò tètè dá sọ́rọ̀ náà ní kíákíá.
Wọ́n yànàná gbogbo owó náà bó ṣe wà ninu ìwé Ilé-ẹjọ́ LMDC.
Owó fífagilé ẹjọ́ tàbí kẹ́ni náà má ṣe yọjú rárá : Wọn yóò san owó ìjókòó tí ó yẹkí wọn ṣe àmọ́, tí ọ̀kan nínú wọn wọ́gilé tàbí tí wọ́n kùnà láti yọjú síbi ìjókòó ìpẹ̀jọ́ náà.
Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ètò jíjẹ́ kí gbogbo èèyàn ní àǹfààní s’étò ìdájọ́, Ilé-ẹjọ́ LMDC ṣ’ètò jíjẹ káwọn èèyàn náà rí ojú rere nípa ṣíṣe ètò idajo náà fún wọn, làwọn ẹjọ́ miiran , wọ́n máa ń ṣ’àtúgbéyẹ̀wọ̀ iye owó tí wọn yóò san, nígbà táwọn ìgbìmọ̀ alábẹṣékélé náà bá ṣ’àtúngbéyẹ̀wò owó náà.
Ẹ lè k’ọ̀wé sílé-ẹjọ́ LMDC fún àtúngbéyẹ̀wò owó tí wọ́n yóò san náà.
Ó tì o, wọn kò ṣ’àtúngbéyẹ̀wò s’ówó tí wọn yóò san f’étò ìṣàkóso.
Ì báà jẹ́ ẹjọ́ nípa ètò okòòwò, Ilé-Ìfowópamọ́ àti ètò mádàndófò, ááwọ̀, ẹjọ́ Bàbá onílé àti ayálégbé ,ááwọ̀ lórí ogún, Gbèsè gbígba, ìbanilórúkọjẹ́, ìṣàkóso ilé alágbolé, ẹjọ́ ẹni tí ó gbani ṣiṣẹ́ àti ẹni tí wọ́n gbà sí iṣẹ́, ááwọ̀ líla ọ̀nà, ìjàmbá àti àìmú-àdéhùn-ṣẹ, àìkọbiara sétò ìlera, fífi-ipá-ṣe-àwọn àkànṣe iṣẹ́, ááwọ̀ ẹbí , ááwọ̀ ogún pínpín, ááwọ̀ nípa ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó àwọn ọkọ̀ orí-omi, Ilé-iṣẹ́,ìpèsè iná ọba , fàákájáa láàrín ẹbí, yápọn-yánrin lórí ọ̀rọ̀ okòòwò àtàwọn ẹ̀sùn kéékèèké mìíràn, nílé –ẹjọ́ LMDC máa ń pèsè àwọn amòfin fáwọn oníbàárà wọn kí wọ́n lè tètè yanjú ááwọ̀ náà ní kíákíá.
Wọ́n á kọ̀wé àkíyèsí sí olùpẹ̀jọ̀ọ́ kí wọ́n lè rán-an létí pé kí ó farahan n’ílé-ẹjọ́ láàrín ọjọ méje tí ó jẹ́ ọjọ́ iṣẹ́ tí ó gbàwé àkíyèsí náà. Níbi tí olùpẹ̀jọ̀ọ́ bá kùnà láti wá, wọn yóò tún kọ̀wé àkíyèsí mìíràn rán létí, kí ó farahàn láàrín ọjọ́ méje, tí ó jẹ́ ọjọ́ iṣẹ́ ìgbà tí ó gbàwé náà. Látàrí pé kò farahàn náà, wọn yóò gbé gbogbo wọn lọ sọ́dọ̀ Adájọ́ tó ń mójútó irú ẹjọ́ báyìí kí olùpẹ̀jọ̀ọ́ wá sọ ìdí rẹ̀ tí kò fi farahàn n’ílé-ẹjọ́.
Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òfin Ilé-ẹjọ́ LMDC ti ọdún 2015, ẹ̀ka ìkẹ́rin(láti orí ìkíní sí ìkẹ́ta) sọ pé, Ilé-ẹjọ́ LMDC yóò ṣèwé àdéhùn ìyànjú ááwọ̀ tí àwọn èèyàn méjéèjì tí wọ́n ń gbéná wojú ara wọn yóò buwọ́lù tàbí kí Adájọ́ -Àgbà ba á paáláṣẹ pé kí wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sílé-ejọ́ gíga lábẹ́ eka kọkànlá àwọn òṣìṣẹ́ ilé-ẹjọ́ tí wọ́n ń f’ipá ṣiṣẹ́ wọn àti lábẹ́ ètò ọ̀rọ̀ aráàlú. Àwọn èèyàn tí wọ́n sọ̀rọ̀ náà yóò farahàn níwájú Adájọ́ lẹ́yìn tí o ti f’ọwọ́ síwèé àdéhùn tàbí ìwé tí wọ́n panupọ̀ lé e lórí, wọn yóò farahàn n’ílé-ẹjọ́ LMDC, Ilé-ẹjọ́ gbangba tàbí ní iyàra ìpẹ̀jọ́ Adájọ́ náà.
Bẹ́ẹ̀ni o, ó ṣeéṣe nípa fifi ipá ṣètò náà lábẹ́ òfin Ilé-ẹjọ́ LMDC ẹ̀ka ìkẹ́rin (ìpele Kínní) ní abala (b) tí ó fààyè gba yíyanjú ááwọ̀ àti tí tọwọ́ –bọ̀wé àdéhùn làwọn Ilé-iṣẹ́ mìíràn tí wọ́n gbé wá s’ílé –ẹjọ́ LMDC tí Adájọ́ ilé-ẹjọ́ ADR buwọ́lú tí o di ìdájọ́ Ilé-ẹjọ́ gíga Ìpínlẹ̀ Èkó.
Ẹ ó ò kọ̀wé sí olùdarí -Àgbà Ilé-ẹjọ́ LMDC, ẹni tí ó kọ̀wé náà yóò gba ìwé tí yóò fi san owó fún ojúlówó ìwé ti ó fẹ́ gbà náà. Bí o bá ṣe ń san owó tán báyìí, Ilé-ìwé náà.
LMDC láwọn ọ́fíìsì láwọn Ilé-ẹjọ́ gíga Ìpínlẹ̀ Èkó pàápàá jùlọ Ilé-ẹjọ́ gíga ìlú Èkó , tí ó wa lẹ́kùn Ìkẹjà, Lágbègbè Ìkẹjà , àti Ilé-ẹjọ́ gíga ìlú Eko , lágbègbè TBS lágbègbè Lagos Island.
Àwọn èèyàn náà lè dá sọ́rọ̀ ìpẹ̀tù -sááwọ̀ náà pẹ̀lú agbẹjọ́rò tabi kí wọ́n gba agbẹjọ́rò Kànkan lásìkò yíysnjú ááwọ̀ náà.
Àjọ LMDC jẹ́ ọ̀nà mìíràn láti yanjú rògbòdìyàn nítùbí-nùbí bí gbígbà ẹni tí yóò yanjú rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, ìtùbí-nùbí, síṣe ìgbéléwọ̀n, Med-Arb , Arb-Meb àtàwọn nǹkan mìíràn.
Ẹni yòówù tí ó bá gbẹ́jọ́ wá l’ẹ́tọ̀ọ́ àti san owó , torí pé , àwọn apẹ̀tù-sááwọ ti wọ́n máa ń pè wá lóòrèkóòrè máa ń gba owó ìṣẹ́ tí wọ́n bá ṣe, èyí wà lábẹ́ akọ́ọ́lẹ̀ kọkàndínlógún Àjọ LMDC fàyè gbà káwọn èèyàn náà san owó.
Wọ́n fàyè gba àwọn apẹ̀tù -sááwọ̀ náà tí wọ́n bá lè yanjú ọ̀rọ̀ náà láì-figbá-kan-bọkan-nínú. Bákan naa, tí ẹnikẹni kò bá kọ̀ pé kí àwọn ẹlẹ́rìí má wà á, àti pé, táwọn ẹlẹ́rìí bá wà , wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ìlànà òfin tí wọ́n gbé kalẹ̀ kí wọn tó lè jẹ́rìí sọ́rọ̀ náà.
Fún irú ọ̀rọ̀ báyìí, àwọn ẹni t'ọ́rọ̀ kàn yóò farahàn níwájú Adájọ́ ADR láti wá sọ ìdí rẹ̀ tí wọn kò fi wá síbi ìjókòó ìpẹ̀tù -sááwọ̀ náà, bẹ́ẹ̀sì ni, wọ́n gbọdọ̀ rí ohun tọ́ka sípé , òhun ló fà á tí wọn kò fi lè yọjú síbi ìjókòó náà.
Ó wà lórí àkókò tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹjọ́ kan wà tí ó jẹ́ pé, ọjọ́ tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ náà ni wọn yóò parí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni, wọn yóò máa sún àwọn ẹjọ́ mìíràn siwaju tí ó lè pẹ́ kí wọ́n tó parí rẹ̀, bóyá láàrín ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù kí wọ́n tó parí rẹ̀.

Àmọ́ , lájọ LMDC, ó n’íye ìgbà tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fáwọn ẹjọ́, ogọ́sàn-án ọjọ́ fáwọn ẹjọ́ tí wọ́n gbé wọlé wéré àti àádọ́ọ́rùn-ún ọjọ́ fáwọn ẹjọ́ tó ti wà làwọn Ilé-ẹjọ́ tẹ̀lé.

Yíyanjúọ̀rọ̀ nítùbí-nùbí wà lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n gbẹ́jọ́ náà wá àti agbẹjọ́rò wọn. Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olùpẹ̀tù-sááwọ̀ tí ó dá wá náà tún lè tètè jẹ́ kí wọ́n parí ááwọ̀ náà kíákíá .
-Awo-mọ̀-sínú –mọ̀-síkùn Ní ìjókòó ADR
-Owó rẹ̀ kòtún wọ́n.
-Ohun tí ẹni tí wọ́n yàn wá síbi ìjókòó náà bá sọ l’abe gé.
Yàtọ̀ sí, ètò fífi ẹjọ́ sùn nílé-ejò tí o máa ń wáyé láàárín gbogbo ènìyàn , ètò ìdájọ́ ADR máa ń wáyé ní bòńkẹ́lẹ́ láàrín gbogbo àwọn èèyàn tí yóò kópa níbẹ̀, wọn yóò tọwọ́ bọ̀wé pé, wọn kò ní sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fáyégbọ́.
Àwọn èèyàn méjèèjì t'ọ́rọ̀ kàn lásìkò ìpẹ̀tù -sááwọ̀ náà ti wọ́n wà níbi ìfàyègbani yíyanjú ọ̀rọ̀ náà nítùbí-ǹ-nùbí’ ni wọn yóò buwọ́lù.
Ètò yíyanjú ọ̀rọ̀ nítùbí-ǹ-nùbí jẹ́ ìwé òfin àdéhùn àwọn èèyàn náà nípa fàdákája, àti fífi ipá ṣe é fún wọn. Níbi tí wọ́n ti gbé ẹjọ́ náà lọ sílé –ẹjọ́ ìpẹ̀tù -sááwọ̀,ìgbésẹ̀ yíyanjú ọ̀rọ̀ náà di ìdájọ́ nílé-ejò.
Níbi t’ẹ́nu àwọn èèyàn náà kò ì tíì kò lásìkò ìpẹ̀tù -sááwọ̀ náà , àwọn èèyàn náà yóò lo ìmọ̀ wọn láti lọ yanjú ẹjọ́ náà lọ́nà mìíràn.
Ètò ìlàjà ní àsìkò táwọn èèyàn t’ẹ́jọ́ náà kàn bá kọ̀ láti yanjú ááwọ̀ náà pẹ̀lú àwọn onílàjà tí ó ju èèyàn kan lọ, bákan náà kí wọ́n pe àwọn èèyàn tí wọ́n kìí ṣe ara wọn,tí yóò mú èdìdì fi di ọ̀rọ̀ ááwọ̀ náà.
Àwọn ááwọ̀ tí ó jẹ mọ́ ètò ọmọ ènìyàn tí ó ṣẹlẹ̀ nípa ẹ̀sùn ọ̀daràn.
-Ẹ̀sùn l’ọ́kọ-laya tí ó jẹ mọ́ kíkọ ara wọn sílẹ̀, fífi ara wọn sílẹ̀ lọ́nà ẹ̀tọ́ ìdájọ́, Píparí ìjà l’ọ́kọ-láya àti ẹni tí yóò láṣẹ láti gba àwọn ọmọ sọ́dọ̀.
- Ẹjọ́ àìlè san gbèsè owó téèyàn jẹ àti yíyanjú ọ̀rọ̀ náà.
-Ẹni tí yóò máa mójútó ọmọ òrukàn lábẹ́ òfin.
-Ẹjọ́ nípa ìṣàkóso ọ̀rọ̀ àwọn Ilé alágbolé.
Bẹ́ẹ̀ni Àwọn èèyàn t’ọ́rọ́ náà kàn lè gbà láti yan onílàjà kan ṣoṣo tàbí ìgbìmọ̀ olùlàjà tí yóò yan olùlàjà kọ̀ọ̀kan, Olùlàjà méjì tàbí kí wọ́n yan olùlàjà tí yóò jẹ́ olórí onílàjà.
Gbogbo àwọn olùkọ́pa ló l’ẹ́tọ̀ọ́ àti rí ara wọn lórí ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé náà tí wọ́n bá ti dásí ètò ìpẹ̀tù -sááwọ̀ náà.
Àwọn èèyàn t’ọ́rọ̀ kàn àti apẹ̀tù-sááwọ̀ náà gbọ́dọ̀ rí i pé, gbogbo àwọn olùkọ́pa tí wọ́n mọ̀ pè, ó yẹ kí wọ́n wà níbẹ̀ ni wọ́n wà níbi ìpàdé náà.
Lẹ́yìn táwọn èèyàn t’ọ́rọ̀ náà kàn, bá ti fẹnukò láti yanjú gbogbo ááwọ̀ náà tán àti onílàjà wọn, wọn yóò fi gbogbo ìgbésẹ̀ tí wọn gbé náà fi ṣ’ọwọ́ sí Ọ̀gá -Àgbà tàbí Ọ̀gá Ìpín tó ń mójútó ẹjọ́ náà tí gbogbo rẹ yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òfin tí wọ́n gbé kalẹ̀ náà.
Níbi tó jẹ́ pé Ilé-iṣẹ́ ní fàákája tí ó ń ṣẹlẹ̀, aṣojú ilé-iṣẹ́ náà yoo mú lẹ́tà t'áwọn òṣìṣẹ́ Ilé-iṣẹ́ náà buwọ́lù wá.
Èyí yóò jẹ́ káwọn aṣojú náà lè kópa, kí ó sì gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan lórúkọ ilé-iṣẹ náà. L’áfikún, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fẹ́ pààrọ̀ aṣojú náà sí ẹlòmíràn tí yóò ṣojú wọn, Ilé-iṣẹ́ náà yóò kọ nǹkan nípa aṣojú tuntun náà tí yóò fi ṣ'ọwọ́ sí Ọ̀gá-Àgbà tó mọ̀ nípa ẹjọ́ náà.
Ipa ọ̀nà ADR jẹ́ ìpín kan lára Ilé-ẹjọ́ tó ń lọ́wọ́ sí oríṣiríṣi ẹjọ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọ́fíìsì tó ń ṣe àkọọ́lè nílé ẹjọ́ gíga ló wà.
Wọn yóò ṣ’àyẹ̀wò gbogbo ẹjọ́ aráàlú fínnífínní kí wọ́n lè mọ èyí tó yẹ fún ADR náà. Ètò yìí ṣeéṣe nígbà tí wọ́n gbé ADR wọnú ìṣàkóso ẹjọ́ àwọn aráàlú lábẹ́ ÀṢẸ 3R11 TI HCLSCPR 2012 ( tí wa di Àṣẹ 5 R 8 tí HCLSPR 2019) tí ó sọ pé : ‘Kí wọ́n ṣàyẹ̀wò fínnífínní gbogbo ẹjọ́ tí ó wà l’ákọọlẹ̀ tí ó yẹ k’ẹ́ka ADR ṣàyẹ̀wò sí, àti èyí tí wọ́n gbé wá s’ílé –ẹjọ́ tó mójútó oríṣiríṣi ẹjọ́ Nìpínlẹ̀ Èkó tàbí ọ̀dọ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ onímọ̀ òfin, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Adájọ́ -Àgbà Ìpínlẹ̀ Èkó yóò máa fi ṣọwọ́ sí wọn, ní gbogbo ìgbà. Ohun tí ipa ọ̀nà ADR ń ṣe nipé, wọ́n fẹ́ kí wọ́n jẹ́ káwọn Ilé-ẹjọ́ fúyẹ́ nípa títẹ dá sọ̀rọ̀ náà àti láì ṣe ojúṣàájú f’áwọn èèyàn méjèèjì t’ọ́rọ̀ náà kàn àtàwọn agbẹjọ́rò naa nípasẹ̀ rírí àwọn èsì nǹkan tí wọ́n fẹ́, lójú-ẹsẹ̀ àti ìlànà ADR tí ó fanimọ́ra.
Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, àwọn ẹjọ́ tí ipa ọ̀nà ADR bá ṣàyẹ̀wò sí kìí t’ọ́jọ́ rárá bíi àwọn ẹjọ́ mìíràn tí wọ́n kò l’áṣẹ lórí rẹ̀ lọ. Yàtò sí pé, ipa ọ̀nà ADR máa ń f’áwọn èèyàn t’ọ́rọ̀ náà Kàn láti yanjú ẹjọ́ wọn ní ìtùbí-ìnùbí, tún máa ń jẹ́ kí ẹjọ́ yá ní kíákíá. Àwọn ohun tí ó wà lábẹ́ yìí làwọn ìgbésẹ̀ tí wọn yóò tẹ̀lé ní ṣísẹ –n-tẹ̀le àwọn ẹjọ́ tàwọn ipa ọ̀nà ADR:- -Níwọ̀n ìgbà tí wọn bá ri pé ẹjọ́ náà dára f’étò ADR, ẹjọ́ náà níbi tí olùjẹ́jọ́ ti gbé ẹjọ́ wà, ilé - ẹjọ́ náà wà fún ìpẹ̀tù - sááwọ . Níbi tí wọn ti ń yanjú ọ̀rọ̀ naa dáadáa, Ìlànà yíyanjú ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn t’ọ́rọ̀ náà kàn àti ọ̀rọ̀ yíyanjú ááwọ̀ náà dáadáa. Níbi táwọn ẹgbẹ́ náà ti kùnà láti yanjú ááwọ̀ náà, ọ̀rọ̀ náà yóò dé iwájú Adájọ́ tó ń ṣàkóso.
Àmọ̀ràn ni pé , káwọn Ilé-iṣẹ́ yan Ọ̀gá-Àgbà ti yóò ṣojú àwọn aláṣẹ Ilé-iṣẹ́ wọn, pàápàá jùlọ àwọn olùdarí àgbà Ìgbìmọ̀ Àjọ Ilé-iṣẹ́ náà. Bákan náà, òṣìṣẹ́ ,náà yóò mú lẹ́tà wá s’áwọn aláṣẹ àti ọ́fíìsì ipa ọ̀nà ADR, kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ Ìpẹ̀tù –sááwọ̀.
Kò sí pé irú aṣọ wo ní wọ́n lè wọ̀, àmọ́, gbogbo àwọn tí yóò bá kópa gbọ́dọ̀ w’ọṣọ dáadáa. Kò pọn dandan k’áwọn agbẹjọ́rò wọ aṣọ àti fìlà tí wọ́n ń dé sórí níbi ìgbẹ́jọ́ ìpẹ̀tù -sááwọ̀ náà.
Níbi tí àwọn èèyàn náà kò tíì fẹnukò lórí yíyanjú ọ̀rọ̀ náà, wọ́n yóò gbé ẹjọ́ náà síwájú Adájọ́ ADR . Látàrí ọ̀rọ̀ yìí , wọn yóò pa ojú ẹjọ́ naa dé wọn yóò gbe dé iwájú Adájọ́ ADR , wọn yóò gbé fáìlì ẹjọ́ náà lọ sọ́dọ̀ Adájọ́ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ìṣàkóso láti tún gbé e yẹ̀wò l’ọ́dọ̀ Adájọ́ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ìṣàkóso láti tún gbé e yẹ̀wọ̀ l’ọ́dọ̀ Adájọ́ tó ń gbẹ́jọ́ náà. Ẹ wo ìlànà 28 R 5 ti HCLSCPR 2019.
Ó tì o. Ètò Olùlàjà náà jẹ́ ọ̀rọ̀ bonńkẹ́lẹ́ láì figbá –kan-bọ̀kan nínú, èyí túnmọ̀ sípé, wọ́n lè pe Olùlàjà náà láti jẹ́rìí n’ílé-ẹjọ́; ohunkóhun tí wọ́n ì báà ṣe níbi ìpẹ̀tù –sááwọ̀ náà, kó lè wúlò l’áwọn Ilé-ẹjọ́ mìíràn lọ́jọ́ iwájú.
Níbi ètò, tí wọn ti yanjú ááwọ̀ díẹ̀ náà díẹ̀, àwọn méjèèjì náà lè yan ètò yíyanjú ááwọ̀ náà lórí ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá parí, kí ó wọ́n tún gba Ilé-ẹjọ́ náà lọ fún yíyanjú àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó lè dá fàákája sílẹ̀. Bákan náà, Àwọn èèyàn t’ọ́rọ̀ kàn náà lé gbà pé kí wọ́n yanjú ááwọ̀ náà, torí ìdí èyí, kí wọ́n gba Ilé-ẹjọ́ lọ.
a. Ilé-iṣẹ́ LMDC máa ń ṣe àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyìí:
b. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìlanilọ́yẹ̀ ìpẹ̀tù -sááwọ̀
c. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìpẹ̀tù -sááwọ̀.
d. Yíyanjú ááwọ̀ lórí ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé.
e. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìṣàkóso ẹjọ́.
ẹ. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀rọ̀ dídá ètò ìdájọ́.
f. Yíyanjú ááwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìṣàkóso.
g. Àtàwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ADR mìíràn.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa máa ń wáyé lẹ́ẹ̀mejì tàbí ẹ̀mẹẹta lọ́dún.
Ẹni yòówù tí ó bá fẹ́ kópa níbi Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà yóò ní ìwé ẹ̀rí Fásitì.
Bẹ́ẹ̀ni o, a máa ń ṣètò kóríyá fáwọn Olùlàjà tuntun tí wọ́n ṣetán àti f’ọwọ́ òkúnkúndún mú iṣẹ́ wọn.
Ẹ lọ s’ílé –ìfowópamọ́ kí ẹ lọ san owó yín, Ilé -Ìfowópamọ́ t’ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó fọwọ́ sí, kí ẹ sì lo orúkọ tí ẹ óò fi san owó yín.
Ẹ jẹ́ kí ó yé e yín pé, Ilé-iṣẹ́ LMDC kò ní gba owó lọ́wọ́ ẹnìkankan o.
Àwọn ohun tí ẹ ó fi san owó náà ni C-541501 àti pé, àwọn nọ́ḿbà tí ẹ ó fi san owó náà ni, 7530000.
Àwọn ibòmíràn tí wọ́n tún ń pawó sápò Ìjọba àtàwọn ohun tí ẹ lè fi san owó náà nii:
* MOU Enforcement 4020215
* ADR Trainings 4020213
* Arbitration fees 4020211
* Mediation fees 4020078
* Administration charges 4020078
* Rental of ADR Facility 4020214
Lẹ́yìn tí ẹ bá ti san owó tán nílé –ìfowópamọ́, ẹ jọ̀wọ́ ẹ gba ìwé tí ẹ fi san owó àti rìsíìtì Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó, lẹ́yìn náà kí ẹ gba ẹ̀ka tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ìṣirò owó lọ l’ájọ LMDC láti lọ gba rìsíìtì ìṣúra Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó láti fi jẹ́rìí pé, wọn san owó sílé –ìfowópamọ́. Lẹ́yìn náà, kí ẹ gba ìpín tó ń ṣ’àkọọ́lẹ̀ ẹjọ́ lọ tàbí ìpín tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ LMDC (àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ADR) lọ.